1 OHUN rere ni lati ma fi ọpẹ fun Oluwa, ati lati ma kọrin si orukọ rẹ, Ọga-ogo:
2 Lati ma fi iṣeun ifẹ rẹ hàn li owurọ, ati otitọ rẹ li alalẹ.
3 Lara ohun-elo orin olokùn mẹwa, ati lara ohun-elo orin mimọ́: lara duru pẹlu iró ti o ni ironu.
4 Nitori iwọ, Oluwa, li o ti mu mi yọ̀ nipa iṣẹ rẹ: emi o ma kọrin iyìn nitori iṣẹ ọwọ rẹ.
5 Oluwa, iṣẹ rẹ ti tobi to! ìro-inu rẹ jinlẹ gidigidi.
6 Ope enia kò mọ̀; bẹ̃li oye eyi kò ye aṣiwere enia.
7 Nigbati awọn enia buburu ba rú bi koriko, ati igbati gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ ba ngberú: ki nwọn ki o le run lailai ni:
8 Ṣugbọn iwọ, Oluwa li ẹniti o ga titi lai.
9 Sa wò o, awọn ọta rẹ, Oluwa, sa wò o, awọn ọta rẹ yio ṣegbe; gbogbo oniṣẹ ẹ̀ṣẹ li a o tuka.
10 Ṣugbọn iwo mi ni iwọ o gbé ga bi iwo agbanrere; ororo titun li a o ta si mi lori.
11 Oju mi pẹlu yio ri ifẹ mi lara awọn ọta mi, eti mi yio si ma gbọ́ ifẹ mi si awọn enia buburu ti o dide si mi.
12 Olododo yio gbà bi igi ọpẹ: yio dàgba bi igi kedari Lebanoni.
13 Awọn ẹniti a gbin ni ile Oluwa, yio gbà ni agbala Ọlọrun wa.
14 Nwọn o ma so eso sibẹ ninu ogbó wọn: nwọn o sanra, nwọn o ma tutù nini;
15 Lati fi hàn pe, Ẹni diduro-ṣinṣin ni Oluwa: on li apata mi, kò si si aiṣododo kan ninu rẹ̀.