O. Daf 45 YCE

Orin Igbeyawo Ọmọ Ọba

1 AIYA mi nhumọ̀ ọ̀ran rere: emi nsọ ohun ti mo ti ṣe, fun ọba ni: kalamu ayawọ akọwe li ahọn mi.

2 Iwọ yanju jù awọn ọmọ enia lọ: a dà ore-ọfẹ si ọ li ète: nitorina li Ọlọrun nbukún fun ọ lailai.

3 San idà rẹ mọ idi rẹ, Alagbara julọ, ani ogo rẹ ati ọlá-nla rẹ.

4 Ati ninu ọlánlá rẹ ma gẹṣin lọ li alafia, nitori otitọ ati ìwa-tutu ati ododo; ọwọ ọtún rẹ yio si kọ́ ọ li ohun ẹ̀ru.

5 Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ.

6 Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni.

7 Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ.

8 Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀.

9 Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri.

10 Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ!

11 Bẹ̃li Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i.

12 Ọmọbinrin Tire ti on ti ọrẹ; ati awọn ọlọrọ̀ ninu awọn enia yio ma bẹ̀bẹ oju-rere rẹ.

13 Ti ogo ti ogo li ọmọbinrin ọba na ninu ile: iṣẹ wura ọnà abẹrẹ li aṣọ rẹ̀.

14 Ninu aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ li a o mu u tọ̀ ọba wá: awọn wundia, ẹgbẹ rẹ̀ ti ntọ̀ ọ lẹhin li a o mu tọ̀ ọ wá.

15 Pẹlu inu didùn ati pẹlu ayọ̀ li a o fi mu wọn wá: nwọn o si wọ̀ ãfin ọba lọ.

16 Nipò awọn baba rẹ li awọn ọmọ rẹ yio wà, ẹniti iwọ o ma fi jẹ oye lori ilẹ gbogbo.

17 Emi o ma ṣe orukọ rẹ ni iranti ni iran gbogbo: nitorina li awọn enia yio ṣe ma yìn ọ lai ati lailai.