O. Daf 68 YCE

Orin ìṣẹ́gun ti Orílẹ̀-Èdè

1 KI Ọlọrun ki o dide, ki a si tú awọn ọta rẹ̀ ka: ki awọn ti o korira rẹ̀ pẹlu, ki nwọn ki o salọ kuro niwaju rẹ̀.

2 Bi ẽfin ti ifẹ lọ, bẹ̃ni ki o fẹ́ wọn lọ; bi ida ti iyọ́ niwaju iná, bẹ̃ni ki enia buburu ki o ṣegbe niwaju Ọlọrun.

3 Ṣugbọn jẹ ki inu awọn olododo ki o dùn; ki nwọn ki o yọ̀ niwaju Ọlọrun. nitõtọ, ki nwọn ki o yọ̀ gidigidi.

4 Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹ kọrin iyin si orukọ rẹ̀: ẹ la ọ̀na fun ẹniti nrekọja li aginju nipa JAH, orukọ rẹ̀, ki ẹ si ma yọ̀ niwaju rẹ̀.

5 Baba awọn alainibaba ati onidajọ awọn opó, li Ọlọrun ni ibujoko rẹ̀ mimọ́.

6 Ọlọrun mu ẹni-ofo joko ninu ile: o mu awọn ti a dè li ẹ̀wọn jade wá si irọra: ṣugbọn awọn ọlọtẹ ni ngbe inu ilẹ gbigbẹ.

7 Ọlọrun, nigbati iwọ jade lọ niwaju awọn enia rẹ, nigbati iwọ nrìn lọ larin aginju.

8 Ilẹ mì, ọrun bọ silẹ niwaju Ọlọrun: ani Sinai tikararẹ̀ mì niwaju Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.

9 Ọlọrun, iwọ li o rán ọ̀pọlọpọ òjo si ilẹ-ini rẹ, nigbati o rẹ̀ ẹ tan, iwọ tù u lara.

10 Ijọ enia rẹ li o tẹ̀do sinu rẹ̀: iwọ Ọlọrun ninu ore rẹ li o ti pèse fun awọn talaka.

11 Oluwa ti sọ̀rọ: ọ̀pọlọpọ si li ogun awọn ẹniti nfi ayọ̀ rohin rẹ̀:

12 Awọn ọba awọn ẹgbẹ ogun sa, nwọn sa lọ: obinrin ti o si joko ni ile ni npin ikogun na.

13 Nigbati ẹnyin dubulẹ larin agbo ẹran, nigbana ni ẹnyin o dabi iyẹ adaba ti a bò ni fadaka, ati ìyẹ́ rẹ̀ pẹlu wura pupa.

14 Nigbati Olodumare tú awọn ọba ká ninu rẹ̀, o dabi òjo-didì ni Salmoni.

15 Òke Ọlọrun li òke Baṣani: òke ti o ni ori pupọ li òke Baṣani.

16 Ẽṣe ti ẹnyin nfi ilara wò, ẹnyin òke, òke na ti Ọlọrun fẹ lati ma gbe? nitõtọ, Oluwa yio ma gbe ibẹ lailai.

17 Ainiye ni kẹkẹ́ ogun Ọlọrun, ani ẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun: Oluwa mbẹ larin wọn, ni Sinai ni ibi mimọ́ nì.

18 Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe.

19 Olubukún li Oluwa, ẹni ti o nba wa gbé ẹrù wa lojojumọ; Ọlọrun ni igbala wa.

20 Ẹniti iṣe Ọlọrun wa li Ọlọrun igbala; ati lọwọ Jehofah Oluwa, li amúwa lọwọ ikú wà.

21 Nitori Ọlọrun yio fọ ori awọn ọta rẹ̀, ati agbari onirun ti iru ẹniti nrìn sibẹ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

22 Oluwa wipe, emi o tun mu pada lati Baṣani wá, emi o tun mu wọn pada lati ibu okun wá.

23 Ki ẹsẹ rẹ ki o le pọ́n ninu ẹ̀jẹ awọn ọta rẹ, ati àhọn awọn aja rẹ ninu rẹ̀ na.

24 Nwọn ti ri ìrin rẹ, Ọlọrun; ani ìrin Ọlọrun mi, Ọba mi, ninu ibi mimọ́ nì.

25 Awọn akọrin lọ niwaju, awọn olohun-elo orin kẹhin; larin awọn ọmọbinrin ti nwọn nlu ìlu.

26 Ẹ fi ibukún fun Ọlọrun li ẹgbẹgbẹ, ani fun Oluwa, ẹnyin ti o ti orisun Israeli wá.

27 Nibẹ ni Benjamini kekere wà, pẹlu olori wọn, awọn ọmọ-alade Juda pẹlu awọn igbimọ wọn, awọn ọmọ-alade Sebuloni, ati awọn ọmọ-alade Naftali.

28 Ọlọrun rẹ ti paṣẹ agbara rẹ: Ọlọrun fi ẹsẹ eyi ti o ti ṣe fun wa mulẹ.

29 Nitori tempili rẹ ni Jerusalemu li awọn ọba yio ma mu ọrẹ fun ọ wá.

30 Ba awọn ẹranko ẽsu wi, ọ̀pọlọpọ awọn akọ-malu, pẹlu awọn ọmọ-malu enia, titi olukulùku yio fi foribalẹ pẹlu ìwọn fadaka: tú awọn enia ti nṣe inu didùn si ogun ka.

31 Awọn ọmọ-alade yio ti Egipti jade wá; nisisiyi ni Etiopia yio nà ọwọ rẹ̀ si Ọlọrun.

32 Ẹ kọrin si Ọlọrun, ẹnyin ijọba aiye; ẹ kọrin iyìn si Oluwa.

33 Si ẹniti ngùn ati ọrun de ọrun atijọ; wò o, o fọhùn rẹ̀, eyi na li ohùn nla.

34 Ẹ jẹwọ agbara fun Ọlọrun; ọlá-nla rẹ̀ wà lori Israeli, ati agbara rẹ̀ mbẹ li awọsanma.

35 Ọlọrun, iwọ li ẹ̀ru lati ibi mimọ́ rẹ wọnni wá: Ọlọrun Israeli li On, ti nfi ilera ati agbara fun awọn enia rẹ̀. Olubukún li Ọlọrun!