O. Daf 104 YCE

Yíyin Ẹlẹ́dàá

1 FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Oluwa, Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọlá ati ọla-nla ni iwọ wọ̀ li aṣọ.

2 Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita:

3 Ẹniti o fi omi ṣe ìti igi-àja iyẹwu rẹ̀: ẹniti o ṣe awọsanma ni kẹkẹ́ rẹ̀, ẹniti o nrìn lori apa iyẹ afẹfẹ:

4 Ẹniti o ṣe ẹfufu ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọ-iná ni iranṣẹ rẹ̀.

5 Ẹniti o fi aiye sọlẹ lori ipilẹ rẹ̀, ti kò le ṣipò pada lailai.

6 Iwọ fi ibu omi bò o mọlẹ bi aṣọ: awọn omi duro lori òke nla.

7 Nipa ibawi rẹ nwọn sá; nipa ohùn ãra rẹ, nwọn yara lọ.

8 Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn.

9 Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ.

10 Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke.

11 Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn;

12 Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi.

13 O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun.

14 O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá;

15 Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le.

16 Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn.

17 Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀.

18 Awọn òke giga li àbo fun awọn ewurẹ igbẹ: ati awọn apata fun awọn ehoro.

19 O da oṣupa fun akokò: õrùn mọ̀ akokò ìwọ rẹ̀.

20 Iwọ ṣe òkunkun, o si di oru: ninu eyiti gbogbo ẹranko igbo nrìn kiri.

21 Awọn ẹgbọrọ kiniun ndún si ohun ọdẹ wọn, nwọn si nwá onjẹ wọn lọwọ Ọlọrun.

22 Õrùn là, nwọn kó ara wọn jọ, nwọn dubulẹ ninu iho wọn.

23 Enia jade lọ si iṣẹ rẹ̀ ati si lãla rẹ̀ titi di aṣalẹ.

24 Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ.

25 Bẹ̃li okun yi ti o tobi, ti o si ni ibò, nibẹ ni ohun ainiye nrakò, ati ẹran kekere ati nla.

26 Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀.

27 Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn.

28 Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn.

29 Iwọ pa oju rẹ mọ́, ara kò rọ̀ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn.

30 Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun.

31 Ogo Oluwa yio wà lailai: Oluwa yio yọ̀ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀.

32 O bojuwo aiye, o si warìrì: o fi ọwọ kàn òke, nwọn si ru ẹ̃fin.

33 Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi.

34 Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa.

35 Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.