1 GBỌ adura mi, Oluwa, ki o si jẹ ki igbe mi ki o wá sọdọ rẹ.
2 Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara mi li ọjọ ti emi wà ninu ipọnju; dẹ eti rẹ si mi: li ọjọ ti mo ba pè, da mi lohùn-lọgan.
3 Nitori ti ọjọ mi run bi ẹ̃fin, egungun mi si jona bi àro.
4 Aiya mi lù, o si rọ bi koriko; tobẹ̃ ti mo gbagbe lati jẹ onjẹ mi.
5 Nitori ohùn ikerora mi, egungun mi lẹ̀ mọ ẹran-ara mi.
6 Emi dabi ẹiyẹ ofú ni iju: emi dabi owiwi ibi ahoro.
7 Emi nṣọra, emi dabi ologoṣẹ nikan ni ori ile.
8 Awọn ọta mi ngàn mi li ọjọ gbogbo; ati awọn ti nṣe ikanra si mi, nwọn fi mi bu.
9 Emi sa jẹ ẽru bi onjẹ, emi si dà ohun mimu mi pọ̀ pẹlu omije.
10 Nitori ikannu ati ibinu rẹ; nitori iwọ ti gbé mi soke, iwọ si gbé mi ṣanlẹ.
11 Ọjọ mi dabi ojiji ti o nfà sẹhin; emi si nrọ bi koriko.
12 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ni yio duro lailai; ati iranti rẹ lati iran dé iran.
13 Iwọ o dide, iwọ o ṣãnu fun Sioni: nitori igba ati ṣe oju-rere si i, nitõtọ, àkoko na de.
14 Nitori ti awọn iranṣẹ rẹ ṣe inu didùn si okuta rẹ̀, nwọn si kãnu erupẹ rẹ̀.
15 Bẹ̃li awọn keferi yio ma bẹ̀ru orukọ Oluwa, ati gbogbo ọba aiye yio ma bẹ̀ru ogo rẹ.
16 Nigbati Oluwa yio gbé Sioni ró, yio farahan ninu ogo rẹ̀.
17 Yio juba adura awọn alaini, kì yio si gàn adura wọn.
18 Eyi li a o kọ fun iran ti mbọ̀; ati awọn enia ti a o da yio ma yìn Oluwa.
19 Nitori ti o wò ilẹ lati òke ibi-mimọ́ rẹ̀ wá; lati ọrun wá ni Oluwa bojuwo aiye;
20 Lati gbọ́ irora ara-tubu; lati tú awọn ti a yàn si ikú silẹ;
21 Lati sọ orukọ Oluwa ni Sioni, ati iyìn rẹ̀ ni Jerusalemu.
22 Nigbati a kó awọn enia jọ pọ̀ ati awọn ijọba, lati ma sìn Oluwa.
23 O rẹ̀ agbara mi silẹ li ọ̀na; o mu ọjọ mi kuru.
24 Emi si wipe, Ọlọrun mi, máṣe mu mi kuro li agbedemeji ọjọ mi: lati irandiran li ọdun rẹ.
25 Lati igba atijọ ni iwọ ti fi ipilẹ aiye sọlẹ: ọrun si ni iṣẹ ọwọ rẹ,
26 Nwọn o ṣegbe, ṣugbọn Iwọ o duro; nitõtọ gbogbo wọn ni yio di ogbó bi aṣọ; bi ẹ̀wu ni iwọ o pàrọ wọn, nwọn o si pàrọ.
27 Ṣugbọn bakanna ni Iwọ, ọdun rẹ kò li opin.
28 Awọn ọmọ awọn iranṣẹ rẹ yio duro pẹ, a o si fi ẹsẹ iru-ọmọ wọn mulẹ niwaju rẹ.