O. Daf 77 YCE

Ìtùnú ní Àkókò Ìpọ́njú

1 EMI fi ohùn mi kigbe si Ọlọrun, ani si Ọlọrun ni mo fi ohùn mi kepè; o si fi eti si mi.

2 Li ọjọ ipọnju mi emi ṣe afẹri Ọlọrun: ọwọ mi nnà li oru, kò si rẹ̀ silẹ: ọkàn mi kọ̀ ati tù ninu.

3 Emi ranti Ọlọrun, emi kẹdun: emi ṣe aroye, ẹmi mi si rẹ̀wẹsi.

4 Iwọ kò fẹ ki emi ki o fi oju ba orun: ẹnu yọ mi tobẹ̃ ti emi kò le sọ̀rọ.

5 Emi ti nrò ọjọ atijọ, ọdun igbani.

6 Mo ranti orin mi li oru: emi mba aiya mi sọ̀rọ: ọkàn mi si nṣe awari jọjọ.

7 Oluwa yio ha ṣa ni tì lailai? kì o si ṣe oju rere mọ́?

8 Anu rẹ̀ ha lọ lailai? ileri rẹ̀ ha yẹ̀ titi lai?

9 Ọlọrun ha gbagbe lati ṣe oju rere? ninu ibinu rẹ̀ o ha sé irọnu ãnu rẹ̀ mọ́?

10 Emi wipe, Eyi li ailera mi! eyi li ọdun ọwọ ọtún Ọga-ogo!

11 Emi o ranti iṣẹ Oluwa: nitõtọ emi o ranti iṣẹ iyanu rẹ atijọ.

12 Ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro gbogbo iṣẹ rẹ pẹlu, emi o si ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ.

13 Ọlọrun, ọ̀na rẹ mbẹ ninu ìwa-mimọ́: tali alagbara ti o tobi bi Ọlọrun?

14 Iwọ li Alagbara ti nṣe iṣẹ iyanu: iwọ li o ti fi ipá rẹ hàn ninu awọn enia.

15 Iwọ li o ti fi apá rẹ rà awọn enia rẹ pada, awọn ọmọ Jakobu ati Josefu.

16 Omi ri ọ, Ọlọrun, omi ri ọ, ẹ̀ru bà wọn: nitõtọ ara ibú kò balẹ.

17 Awọsanma dà omi silẹ: ojusanma rán iró jade: ọfà rẹ jade lọ pẹlu.

18 Ohùn ãrá rẹ nsan li ọrun: manamana nkọ si aiye, ilẹ nwa-rìri, o si mì.

19 Ọ̀na rẹ mbẹ li okun, ati ipa rẹ ninu awọn omi nla, ipasẹ rẹ li a kò si mọ̀.

20 Iwọ dà awọn enia rẹ bi ọ̀wọ-ẹran nipa ọwọ Mose ati Aaroni.