O. Daf 135 YCE

Orin Ìyìn

1 Ẹ yìn Oluwa, Ẹ yìn orukọ Oluwa; ẹ yìn i, ẹnyin iranṣẹ Oluwa.

2 Ẹnyin ti nduro ni ile Oluwa, ninu agbalá ile Ọlọrun wa.

3 Ẹ yìn Oluwa: nitori ti Oluwa ṣeun; ẹ kọrin iyìn si orukọ rẹ̀; ni orin ti o dùn.

4 Nitori ti Oluwa ti yàn Jakobu fun ara rẹ̀; ani Israeli fun iṣura ãyo rẹ̀.

5 Nitori ti emi mọ̀ pe Oluwa tobi, ati pe Oluwa jù gbogbo oriṣa lọ.

6 Ohunkohun ti o wù Oluwa, on ni iṣe li ọrun, ati li aiye, li okun, ati ni ọgbun gbogbo.

7 O mu ikũku gòke lati opin ilẹ wá: o da manamana fun òjo: o nmu afẹfẹ ti inu ile iṣura rẹ̀ wá.

8 Ẹniti o kọlù awọn akọbi Egipti, ati ti enia ati ti ẹranko.

9 Ẹniti o rán àmi ati iṣẹ iyanu si ãrin rẹ, iwọ Egipti, si ara Farao, ati si ara awọn iranṣẹ rẹ̀ gbogbo.

10 Ẹniti o kọlu awọn orilẹ-ède pupọ̀, ti o si pa awọn alagbara ọba.

11 Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani:

12 O si fi ilẹ wọn funni ni ini, ini fun Israeli, enia rẹ̀.

13 Oluwa, orukọ rẹ duro lailai; iranti rẹ Oluwa, lati iran-diran.

14 Nitori ti Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si ṣe iyọ́nu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀,

15 Fadaka on wura li ere awọn keferi, iṣẹ ọwọ enia.

16 Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ; nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò fi riran.

17 Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò fi gbọran; bẹ̃ni kò si ẽmi kan li ẹnu wọn.

18 Awọn ti o ṣe wọn dabi wọn: bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.

19 Ẹnyin arale Israeli, ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin arale Aaroni, ẹ fi ibukún fun Oluwa.

20 Ẹnyin arale Lefi, ẹ fi ibukún fun Oluwa; ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ fi ibukún fun Oluwa.

21 Olubukún li Oluwa, lati Sioni wá, ti ngbe Jerusalemu. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.