1 EṢE ti iwọ fi duro li òkere rere, Oluwa; ẽṣe ti iwọ fi fi ara pamọ́ ni igba ipọnju.
2 Ninu igberaga li enia buburu nṣe inunibini si awọn talaka: ninu arekereke ti nwọn rò ni ki a ti mu wọn.
3 Nitori enia buburu nṣogo ifẹ ọkàn rẹ̀, o si nsure fun olojukokoro, o si nkẹgan Oluwa.
4 Enia buburu, nipa igberaga oju rẹ̀, kò fẹ ṣe afẹri Ọlọrun: Ọlọrun kò si ni gbogbo ironu rẹ̀.
5 Ọ̀na rẹ̀ nlọ siwaju nigbagbogbo; idajọ rẹ jina rere kuro li oju rẹ̀; gbogbo awọn ọta rẹ̀ li o nfẹ̀ si.
6 O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, A kì yio ṣi mi ni ipò: lati irandiran emi kì yio si ninu ipọnju.
7 Ẹnu rẹ̀ kún fun egún, ati fun ẹ̀tan, ati fun itanjẹ: ìwa-ìka ati ìwa-asan mbẹ labẹ ahọn rẹ̀.
8 O joko ni buba ni ileto wọnni: ni ibi ìkọkọ wọnni li o npa awọn alaiṣẹ̀: oju rẹ̀ nṣọ́ awọn talaka nikọkọ.
9 O lùmọ ni ibi ìkọkọ bi kiniun ninu pantiri: o lùmọ lati mu talaka: a si mu talaka, nigbati o ba fà a sinu àwọn rẹ̀.
10 O ba, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ki talaka ki o le bọ́ si ọwọ agbara rẹ̀.
11 O ti wi li ọkàn rẹ̀ pe, Ọlọrun ti gbagbe: o pa oju rẹ̀ mọ́; on kì yio ri i lailai.
12 Dide, Oluwa; Ọlọrun, gbé ọwọ rẹ soke: máṣe gbagbe olupọnju.
13 Ẽṣe ti enia buburu fi ngàn Ọlọrun? o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Iwọ kì yio bère.
14 Iwọ ti ri i; nitori iwọ nwò ìwa-ìka ati iwọsi, lati fi ọ̀ran na le ọwọ rẹ; talaka fi ara rẹ̀ le ọ lọwọ; iwọ li oluranlọwọ alaini-baba.
15 Ṣẹ́ apa enia buburu, ati ti ọkunrin ibi nì: iwọ wá ìwa-buburu rẹ̀ ri, titi iwọ kì yio fi ri i mọ́.
16 Oluwa li ọba lai ati lailai: awọn keferi run kuro ni ilẹ rẹ̀.
17 Oluwa, iwọ ti gbọ́ ifẹ onirẹlẹ: iwọ o mu ọkàn wọn duro, iwọ o dẹ eti rẹ si i.
18 Lati ṣe idajọ alaini-baba ati ẹni-inilara, ki ọkunrin aiye ki o máṣe daiya-fo-ni mọ́.