1 GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi.
2 Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ.
3 Nitori iwọ li o ti nṣe àbo fun mi, ati ile-iṣọ agbara lọwọ ọta nì.
4 Emi o joko ninu agọ rẹ lailai: jẹ ki emi ri àbo ni iyẹ-apa rẹ.
5 Nitoripe iwọ, Ọlọrun, li o ti gbọ́ ẹjẹ́ mi: iwọ ti fi ogún awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ fun mi.
6 Iwọ o fa ẹmi ọba gùn: ati ọjọ ọdun rẹ̀ bi atiran-diran.
7 On o ma gbe iwaju Ọlọrun lailai; pèse ãnu ati otitọ, ti yio ma ṣe itọju rẹ̀.
8 Bẹ̃li emi o ma kọrin iyìn si orukọ rẹ lailai, ki emi ki o le ma san ẹjẹ́ mi li ojojumọ.