1 OLUWA, aiya mi kò gbega, bẹ̃li oju mi kò gbé soke: bẹ̃li emi kò fi ọwọ mi le ọ̀ran nla, tabi le ohun ti o ga jù mi lọ.
2 Nitõtọ emi mu ọkàn mi simi, mo si mu u dakẹjẹ, bi ọmọ ti a ti ọwọ iya rẹ̀ gbà li ẹnu ọmu: ọkàn mi ri bi ọmọ ti a já li ẹnu ọmu.
3 Israeli, iwọ ni ireti lọdọ Oluwa lati isisiyi lọ ati lailai.