1 ỌLỌRUN Olodumare, ani Oluwa li o ti sọ̀rọ, o si pè aiye lati ìla-õrun wá titi o fi de ìwọ rẹ̀.
2 Lati Sioni wá, pipé ẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ.
3 Ọlọrun wa mbọ̀, kì yio si dakẹ; iná yio ma jó niwaju rẹ̀, ẹfufu lile yio si ma ja yi i ka kiri.
4 Yio si kọ si awọn ọrun lati òke wá, ati si aiye, ki o le ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀.
5 Kó awọn enia mimọ́ mi jọ pọ̀ si ọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi da majẹmu.
6 Awọn ọrun yio si sọ̀rọ ododo rẹ̀: nitori Ọlọrun tikararẹ̀ li onidajọ.
7 Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si sọ̀rọ; Israeli, emi o si jẹri si ọ: emi li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ.
8 Emi kì yio ba ọ wi nitori ẹbọ rẹ, ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ wà niwaju mi nigbagbogbo.
9 Emi kì yio mu akọ-malu lati ile rẹ jade, tabi obukọ ninu agbo-ẹran rẹ:
10 Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke.
11 Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi.
12 Bi ebi npa mi, emi kì yio sọ fun ọ: nitori pe aiye ni ti emi, ati ẹkún inu rẹ̀.
13 Emi o ha jẹ ẹran malu, tabi emi a ma mu ẹ̀jẹ ewurẹ bi?
14 Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo.
15 Ki o si kepè mi ni ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo.
16 Ṣugbọn Ọlọrun wi fun enia buburu pe, Kini iwọ ni ifi ṣe lati ma sọ̀rọ ilana mi, tabi ti iwọ fi nmu majẹmu mi li ẹnu rẹ?
17 Wò o, iwọ sa korira ẹkọ́, iwọ si ti ṣá ọ̀rọ mi tì lẹhin rẹ.
18 Nigbati iwọ ri olè, nigbana ni iwọ ba a mọ̀ ọ pọ̀, iwọ si ba awọn àgbere ṣe ajọpin.
19 Iwọ fi ẹnu rẹ fun buburu, ati ahọn rẹ npete ẹ̀tan.
20 Iwọ joko, iwọ si sọ̀rọ si arakunrin rẹ: iwọ mba orukọ ọmọ iya rẹ jẹ.
21 Nkan wọnyi ni iwọ ṣe emi si dakẹ; iwọ ṣebi emi tilẹ dabi iru iwọ tikararẹ; emi o ba ọ wi, emi o si kà wọn li ẹsẹ-ẹsẹ ni oju rẹ.
22 Njẹ rò eyi, ẹnyin ti o gbagbe Ọlọrun, ki emi ki o má ba fà nyin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ti kò si olugbala.
23 Ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ iyìn, o yìn mi logo: ati ẹniti o ba mu ọ̀na ọ̀rọ rẹ̀ tọ́ li emi o fi igbala Ọlọrun hàn fun.