1 OLUWA, iwọ ti wadi mi, iwọ si ti mọ̀ mi.
2 Iwọ mọ̀ ijoko mi ati idide mi, iwọ mọ̀ iro mi li ọ̀na jijin rére.
3 Iwọ yi ipa ọ̀na mi ká ati ibulẹ mi, gbogbo ọ̀na mi si di mimọ̀ fun ọ.
4 Nitori ti kò si ọ̀rọ kan li ahọn mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ patapata.
5 Iwọ sé mi mọ lẹhin ati niwaju, iwọ si fi ọwọ rẹ le mi.
6 Iru ìmọ yi ṣe ohun iyanu fun mi jù; o ga, emi kò le mọ̀ ọ.
7 Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ?
8 Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ.
9 Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun;
10 Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu.
11 Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka.
12 Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ.
13 Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi.
14 Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju.
15 Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye.
16 Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi.
17 Ọlọrun, ìro inu rẹ ti ṣe iye-biye to fun mi, iye wọn ti pọ̀ to!
18 Emi iba kà wọn, nwọn jù iyanrin lọ ni iye: nigbati mo ba jí, emi wà lọdọ rẹ sibẹ.
19 Ọlọrun iba jẹ pa enia buburu nitõtọ: nitorina kuro lọdọ mi ẹnyin ọkunrin ẹ̀jẹ.
20 Ẹniti nfi inu buburu sọ̀rọ si ọ, awọn ọta rẹ npè orukọ rẹ li asan!
21 Oluwa, njẹ emi kò korira awọn ti o korira rẹ? njẹ inu mi kò ha si bajẹ si awọn ti o dide si ọ?
22 Emi korira wọn li àkotan: emi kà wọn si ọta mi.
23 Ọlọrun, wadi mi, ki o si mọ̀ aiya mi: dán mi wò, ki o si mọ̀ ìro-inu mi:
24 Ki o si wò bi ipa-ọ̀na buburu kan ba wà ninu mi, ki o si fi ẹsẹ mi le ọ̀na ainipẹkun.