1 LATI inu ibu wá li emi kepe ọ, Oluwa.
2 Oluwa, gbohùn mi, jẹ ki eti rẹ ki o tẹ́ silẹ si ohùn ẹ̀bẹ mi.
3 Oluwa, ibaṣepe iwọ a mã sami ẹ̀ṣẹ, Oluwa, tani iba duro?
4 Nitori idariji wà lọdọ rẹ, ki a le ma bẹ̀ru rẹ.
5 Emi duro dè Oluwa, ọkàn mi duro, ati ninu ọ̀rọ rẹ̀ li emi nṣe ireti.
6 Ọkàn mi duro dè Oluwa, jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ, ani jù awọn ti nṣọ́na owurọ lọ.
7 Israeli iwọ ni ireti niti Oluwa: nitori pe lọdọ Oluwa li ãnu wà, ati lọdọ rẹ̀ li ọ̀pọlọpọ idande wà.
8 On o si da Israeli nidè kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo,