O. Daf 40 YCE

Orin ìyìn

1 NI diduro emi duro de Oluwa; o si dẹti si mi, o si gbohun ẹkún mi.

2 O si mu mi gòke pẹlu lati inu iho iparun jade wá, lati inu erupẹ ẹrẹ̀, o si fi ẹsẹ mi ka ori apata, o si fi iṣisẹ mi lelẹ.

3 O si fi orin titun si mi li ẹnu, ani orin iyìn si Ọlọrun wa: ọ̀pọ enia ni yio ri i, ti yio si bẹ̀ru, ti yio si gbẹkẹle Oluwa.

4 Ibukún ni fun ọkunrin na ti o fi Oluwa ṣe igbẹkẹle rẹ̀, ti kò si ka onirera si, tabi iru awọn ti nyà si iha eke.

5 Oluwa Ọlọrun mi ọ̀pọlọpọ ni iṣẹ iyanu ti iwọ ti nṣe, ati ìro inu rẹ sipa ti wa: a kò le kà wọn fun ọ li ẹsẹ-ẹsẹ: bi emi o wi ti emi o sọ̀rọ wọn, nwọn jù ohun kikà lọ.

6 Ẹbọ ati ọrẹ iwọ kò fẹ: eti mi ni iwọ ti ṣi: ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ-ẹbọ ẹ̀ṣẹ on ni iwọ kò bère.

7 Nigbana ni mo wipe, Kiyesi i, emi de: ninu àpo-iwe nì li a gbe kọwe mi pe,

8 Inu mi dùn lati ṣe ifẹ rẹ, Ọlọrun mi, nitõtọ, ofin rẹ mbẹ li aiya mi.

9 Emi ti wãsu ododo ninu awujọ nla: kiyesi i, emi kò pa ete mi mọ́, Oluwa, iwọ mọ̀.

10 Emi kò fi ododo rẹ sin li aiya mi, emi o sọ̀rọ otitọ ati igbala rẹ: emi kò si pa iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ mọ́ kuro lọdọ ijọ nla nì.

11 Iwọ máṣe fa ãnu rẹ ti o rọnu sẹhin kuro lọdọ mi, Oluwa: ki iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ ki o ma pa mi mọ́ nigbagbogbo.

Adura Ìrànlọ́wọ́

12 Nitoripe ainiye ibi li o yika kiri: ẹ̀ṣẹ mi dì mọ mi, bẹ̃li emi kò le gbé oju wò oke, nwọn jù irun ori mi lọ: nitorina aiya mi npá mi.

13 Ki o wù ọ, Oluwa, lati gbà mi: Oluwa, yara lati ràn mi lọwọ,

14 Ki oju ki o tì wọn, ki nwọn ki o si damu pọ̀, awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run; ki a lé wọn pada sẹhin, ki a si dojuti awọn ti nfẹ mi ni ibi.

15 Ki nwọn ki o di ofo fun ère itiju wọn, awọn ti nwi fun mi pe, A! a!

16 Ki gbogbo awọn ti nwá ọ, ki o ma yọ̀, ki inu wọn ki o si ma dùn sipa tirẹ: ki gbogbo awọn ti o si fẹ igbala rẹ ki o ma wi nigbagbogbo pe, Gbigbega li Oluwa.

17 Ṣugbọn talaka ati alaini li emi; Oluwa si nṣe iranti mi; iwọ ni iranlọwọ mi ati olugbala mi: máṣe pẹ titi, Ọlọrun mi.