1 ỌLỌRUN, ẽṣe ti iwọ fi ta wa nù titi lai! ẽṣe ti ibinu rẹ fi nrú si agutan papa rẹ?
2 Ranti ijọ enia rẹ ti iwọ ti rà nigba atijọ; ilẹ-ini rẹ ti iwọ ti rà pada; òke Sioni yi, ninu eyi ti iwọ ngbe.
3 Gbé ẹsẹ rẹ soke si ahoro lailai nì; ani si gbogbo eyiti ọta ti fi buburu ṣe ni ibi-mimọ́.
4 Awọn ọta rẹ nke ramu-ramu lãrin ijọ enia rẹ; nwọn gbé asia wọn soke fun àmi.
5 Nwọn dabi ọkunrin ti ngbé akeke rẹ̀ soke ninu igbo didi,
6 Ṣugbọn nisisiyi iṣẹ ọnà finfin ni nwọn fi akeke ati òlu wó lulẹ pọ̀ li ẹ̃kan.
7 Nwọn tinabọ ibi-mimọ́ rẹ, ni wiwo ibujoko orukọ rẹ lulẹ, nwọn sọ ọ di ẽri.
8 Nwọn wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a run wọn pọ̀: nwọn ti kun gbogbo ile Ọlọrun ni ilẹ na.
9 Awa kò ri àmi wa: kò si woli kan mọ́: bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi yio ti pẹ to.
10 Ọlọrun, ọta yio ti kẹgan pẹ to? ki ọta ki o ha ma sọ̀rọ òdi si orukọ rẹ lailai?
11 Ẽṣe ti iwọ fi fa ọwọ rẹ sẹhin, ani ọwọ ọtún rẹ? fà a yọ jade kuro li õkan aiya rẹ ki o si pa a run.
12 Nitori Ọlọrun li Ọba mi li atijọ wá, ti nṣiṣẹ igbala lãrin aiye.
13 Iwọ li o ti yà okun ni meji nipa agbara rẹ: iwọ ti fọ́ ori awọn erinmi ninu omi.
14 Iwọ fọ́ ori Lefiatani tũtu, o si fi i ṣe onjẹ fun awọn ti ngbe inu ijù.
15 Iwọ là orisun ati iṣan-omi: iwọ gbẹ awọn odò nla.
16 Tirẹ li ọsán, tirẹ li oru pẹlu: iwọ li o ti pèse imọlẹ ati õrun.
17 Iwọ li o ti pàla eti aiye: iwọ li o ṣe igba ẹ̀run ati igba otutu.
18 Ranti eyi, Oluwa, pe ọta nkẹgàn, ati pe awọn enia buburu nsọ̀rọ odi si orukọ rẹ.
19 Máṣe fi ọkàn àdaba rẹ le ẹranko igbẹ lọwọ: máṣe gbagbe ijọ awọn talaka rẹ lailai.
20 Juba majẹmu nì: nitori ibi òkunkun aiye wọnni o kún fun ibugbe ìka.
21 Máṣe jẹ ki ẹniti a ni lara ki o pada ni ìtiju; jẹ ki talaka ati alaini ki o yìn orukọ rẹ.
22 Ọlọrun, dide, gbà ẹjọ ara rẹ rò: ranti bi aṣiwere enia ti ngàn ọ lojojumọ.
23 Máṣe gbagbe ohùn awọn ọta rẹ: irọkẹ̀kẹ awọn ti o dide si ọ npọ̀ si i nigbagbogbo.