1 EMI o ma yìn ọ tinu-tinu mi gbogbo; niwaju awọn oriṣa li emi o ma kọrin iyìn si ọ.
2 Emi o ma gbadura siha tempili mimọ́ rẹ, emi o si ma yìn orukọ rẹ nitori iṣeun-ifẹ rẹ ati otitọ rẹ; nitori iwọ gbé ọ̀rọ rẹ ga jù gbogbo orukọ rẹ lọ.
3 Li ọjọ ti mo kepè, iwọ da mi lohùn, iwọ si fi ipa mu mi lara le li ọkàn mi.
4 Gbogbo awọn ọba aiye yio yìn ọ, Oluwa, nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ ẹnu rẹ.
5 Nitõtọ, nwọn o ma kọrin ni ipa-ọ̀na Oluwa: nitori pe nla li ogo Oluwa.
6 Bi Oluwa tilẹ ga, sibẹ o juba awọn onirẹlẹ; ṣugbọn agberaga li o mọ̀ li òkere rére.
7 Bi emi tilẹ nrìn ninu ipọnju, iwọ ni yio sọ mi di ãye: iwọ o nà ọwọ rẹ si ibinu awọn ọta mi, ọwọ ọtún rẹ yio si gbà mi.
8 Oluwa yio ṣe ohun ti iṣe ti emi li aṣepe: Oluwa, ãnu rẹ duro lailai: máṣe kọ̀ iṣẹ ọwọ ara rẹ silẹ.