1 ỌLỌRUN li àbo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju.
2 Nitorina li awa kì yio bẹ̀ru, bi a tilẹ ṣi aiye ni idi, ti a si ṣi awọn oke nla nipò lọ si inu okun:
3 Bi omi rẹ̀ tilẹ nho ti o si nru, bi awọn òke nla tilẹ nmì nipa ọwọ bibì rẹ̀.
4 Odò nla kan wà, ṣiṣan eyiti yio mu inu ilu Ọlọrun dùn, ibi mimọ́ agọ wọnni ti Ọga-ogo.
5 Ọlọrun mbẹ li arin rẹ̀; a kì yio ṣi i ni idi: Ọlọrun yio ràn a lọwọ ni kutukutu owurọ.
6 Awọn keferi nbinu, awọn ilẹ ọba ṣidi: o fọhun rẹ̀, aiye yọ́.
7 Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.
8 Ẹ wá wò awọn iṣẹ Oluwa, iru ahoro ti o ṣe ni aiye.
9 O mu ọ̀tẹ tan de opin aiye; o ṣẹ́ ọrun, o si ke ọ̀kọ meji; o si fi kẹkẹ́ ogun jona.
10 Ẹ duro jẹ, ki ẹ si mọ̀ pe emi li Ọlọrun, a o gbé mi ga ninu awọn keferi, a o gbé mi ga li aiye.
11 Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.