O. Daf 27 YCE

Adura Ìyìn

1 OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bẹ̀ru? Oluwa li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi?

2 Nigbati awọn enia buburu, ani awọn ọta mi ati awọn abinuku mi sunmọ mi lati jẹ ẹran ara mi, nwọn kọsẹ, nwọn si ṣubu.

3 Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le.

4 Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀.

5 Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata.

6 Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa.

7 Gbọ́, Oluwa, nigbati mo ba fi ohùn mi pè: ṣanu fun mi pẹlu, ki o si da mi li ohùn.

8 Nigbati o wipe, Ẹ ma wa oju mi; ọkàn mi wi fun ọ pe, Oju rẹ, Oluwa, li emi o ma wá.

9 Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi; máṣe fi ibinu ṣa iranṣẹ rẹ tì: iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi; má fi mi silẹ, bẹ̃ni ki o máṣe kọ̀ mi, Ọlọrun igbala mi.

10 Nigbati baba ati iya mi kọ̀ mi silẹ, nigbana ni Oluwa yio tẹwọgbà mi.

11 Kọ́ mi li ọ̀na rẹ, Oluwa, ki o si tọ́ mi li ọ̀na titọ, nitori awọn ọta mi.

12 Máṣe fi mi le ifẹ awọn ọta mi lọwọ; nitori awọn ẹlẹri eke dide si mi, ati iru awọn ti nmí imí-ìkà.

13 Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alãye.

14 Duro de Oluwa; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni, duro de Oluwa.