1 ỌLỌRUN, iwọ li awa fi ọpẹ fun, iwọ li awa fi ọpẹ fun nitori orukọ rẹ sunmọ itosi, iṣẹ iyanu rẹ fi hàn.
2 Nigbati akokò mi ba de, emi o fi otitọ ṣe idajọ.
3 Aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀ warìri: emi li o rù ọwọ̀n rẹ̀.
4 Emi wi fun awọn agberaga pe, Ẹ máṣe gbéraga mọ́: ati fun awọn enia buburu pe, Ẹ máṣe gbé iwo nì soke.
5 Ẹ máṣe gbé iwo nyin ga: ẹ máṣe fi ọrùn lile sọ̀rọ.
6 Nitori ti igbega kò ti ìla-õrùn wá, tabi ni ìwọ-õrùn, bẹ̃ni kì iṣe lati gusu wá.
7 Ṣugbọn Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke.
8 Nitoripe li ọwọ Oluwa li ago kan wà, ọti-waini na si pọ́n: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rẹ̀; ṣugbọn gèdẹgẹdẹ rẹ̀, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu.
9 Ṣugbọn emi o ma sọ titi lai, emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun Jakobu.
10 Gbogbo iwo awọn enia buburu li emi o ke kuro; ṣugbọn iwo awọn olododo li emi o gbé soke.