1 ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀.
2 Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla.
3 A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀.
4 Sa wò o, awọn ọba pejọ pọ̀, nwọn jumọ nkọja lọ.
5 Nwọn ri i, bẹ̃li ẹnu yà wọn; a yọ wọn lẹnu, nwọn yara lọ.
6 Ẹ̀ru bà wọn nibẹ, ati irora bi obinrin ti nrọbi.
7 Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi.
8 Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai.
9 Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ.
10 Ọlọrun, gẹgẹ bi orukọ rẹ, bẹ̃ni iyìn rẹ de opin aiye: ọwọ ọtún rẹ kún fun ododo.
11 Ki òke Sioni ki o yọ̀, ki inu awọn ọmọbinrin Juda ki o dùn, nitori idajọ rẹ.
12 Rìn Sioni kiri, ki o si yi i ka: kà ile-iṣọ rẹ̀.
13 Kiyesi odi rẹ̀, kiyesi ãfin rẹ̀ wọnni; ki ẹnyin le ma wi fun iran atẹle nyin.
14 Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú.