O. Daf 7 YCE

Ọlọrun Onídàájọ́ Òdodo

1 OLUWA, Ọlọrun mi, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: gbà mi lọwọ gbogbo awọn ti nṣe inunibini si mi, ki o si yọ mi kuro.

2 Ki o má ba fa ọkàn mi ya bi kiniun, a yà a pẹrẹpẹrẹ, nigbati kò si oluranlọwọ.

3 Oluwa, Ọlọrun mi, bi mo ba ṣe eyi, bi ẹ̀ṣẹ ba mbẹ li ọwọ mi;

4 Bi mo ba fi ibi san a fun ẹniti temi tirẹ̀ wà li alafia; (nitõtọ ẹniti nṣe ọta mi li ainidi, emi tilẹ gbà a là:)

5 Jẹ ki ọta ki o ṣe inunibini si ọkàn mi, ki o si mu u; ki o tẹ̀ ẹmi mi mọlẹ, ki o si fi ọlá mi le inu ekuru.

6 Dide Oluwa, ni ibinu rẹ! gbé ara rẹ soke nitori ikannu awọn ọta mi: ki iwọ ki o si jí fun mi si idajọ ti iwọ ti pa li aṣẹ.

7 Bẹ̃ni ijọ awọn enia yio yi ọ ká kiri; njẹ nitori wọn iwọ pada si òke.

8 Oluwa yio ṣe idajọ awọn enia: Oluwa ṣe idajọ mi, gẹgẹ bi ododo mi, ati gẹgẹ bi ìwatitọ inu mi.

9 Jẹ ki ìwa-buburu awọn enia buburu ki o de opin: ṣugbọn mu olotitọ duro: nitoriti Ọlọrun olododo li o ndan aiya ati inu wò.

10 Abo mi mbẹ lọdọ Ọlọrun ti o nṣe igbala olotitọ li aiya.

11 Ọlọrun li onidajọ ododo, Ọlọrun si nbinu si enia buburu lojojumọ:

12 Bi on kò ba yipada, yio si pọ́n idà rẹ̀ mu: o ti fà ọrun rẹ̀ le na, o ti mura rẹ̀ silẹ.

13 O si ti pèse elo ikú silẹ fun u; o ti ṣe awọn ọfa rẹ̀ ni oniná.

14 Kiyesi i, o nrọbi ẹ̀ṣẹ, o si loyun ìwa-ìka, o si bí eké jade.

15 O ti wà ọ̀fin, o gbẹ́ ẹ, o si bọ́ sinu iho ti on na wà.

16 Ìwa-ika rẹ̀ yio si pada si ori ara rẹ̀, ati ìwa-agbara rẹ̀ yio si sọ̀kalẹ bọ̀ si atari ara rẹ̀.

17 Emi o yìn Oluwa gẹgẹ bi ododo rẹ̀: emi o si kọrin iyìn si orukọ Oluwa Ọga-ogo julọ.