1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
2 Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn?
3 Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo.
4 Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò.
5 Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ.
6 Awa ti ṣẹ̀ pẹlu awọn baba wa, awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe buburu.
7 Iṣẹ iyanu rẹ kò yé awọn baba wa ni Egipti; nwọn kò ranti ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ; ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si ọ nibi okun, ani nibi Okun pupa.