5 Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, lori awọn ọrun: ati ogo rẹ lori gbogbo aiye.
6 Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là: fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si da mi lohùn.
7 Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu.
8 Ti emi ni Gileadi: ti emi ni Manasse: Efraimu pẹlu li agbara ori mi: Juda li olofin mi:
9 Moabu ni ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bata mi si; lori Filistia li emi o ho iho-ayọ̀.
10 Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi ni? tani yio sìn mi lọ si Edomu?
11 Iwọ Ọlọrun ha kọ́, ẹniti o ti ṣa wa tì? Ọlọrun, iwọ kì yio si ba awọn ogun wa jade lọ?