1 MÁṢE pa ẹnu rẹ mọ́, Ọlọrun iyìn mi;
2 Nitori ti ẹnu awọn enia buburu, ati ẹnu awọn ẹlẹtan yà silẹ si mi: nwọn ti fi ahọn eke sọ̀rọ si mi.
3 Nwọn si fi ọ̀rọ irira yi mi ka kiri; nwọn si mba mi ja li ainidi.
4 Nipo ifẹ mi nwọn nṣe ọta mi: ṣugbọn emi ngba adura.