14 Ki a ma ranti ẹ̀ṣẹ awọn baba rẹ̀ lọdọ Oluwa; má si jẹ ki a nù ẹ̀ṣẹ iya rẹ̀ nù.
15 Jẹ ki nwọn ki o wà niwaju Oluwa nigbagbogbo, ki o le ke iranti wọn kuro lori ilẹ.
16 Nitori ti kò ranti lati ṣãnu, ṣugbọn o ṣe inunibini si ọkunrin talaka ati olupọnju nì, ki o le pa onirobinujẹ-ọkàn.
17 Bi o ti fẹ egun, bẹ̃ni ki o de si i: bi inu rẹ̀ kò ti dùn si ire, bẹ̃ni ki o jina si i.
18 Bi o ti fi egun wọ ara rẹ li aṣọ bi ẹwu rẹ̀, bẹ̃ni ki o wá si inu rẹ̀ bi omi, ati bi orõro sinu egungun rẹ̀.
19 Jẹ ki o ri fun u bi aṣọ ti o bò o lara, ati fun àmure ti o fi gbajá nigbagbogbo.
20 Eyi li ère awọn ọta mi lati ọwọ Oluwa wá, ati ti awọn ti nsọ̀rọ ibi si ọkàn mi.