23 Emi nkọja lọ bi ojiji ti o nfà sẹhin, emi ntì soke tì sodò bi eṣú.
24 Ẽkun mi di ailera nitori igbawẹ; ẹran-ara mi si gbẹ nitori ailọra.
25 Emi di ẹ̀gan fun wọn pẹlu: nigbati nwọn wò mi, nwọn mi ori wọn.
26 Ràn mi lọwọ, Oluwa Ọlọrun mi: gbà mi gẹgẹ bi ãnu rẹ.
27 Ki nwọn ki o le mọ̀ pe ọwọ rẹ li eyi; pe Iwọ, Oluwa, li o ṣe e.
28 Nwọn o ma gegun, ṣugbọn iwọ ma sure: nigbati nwọn ba dide, ki oju ki o tì wọn; ṣugbọn iranṣẹ rẹ yio yọ̀.
29 Jẹ ki a fi ìtiju wọ̀ awọn ọta mi li aṣọ, ki nwọn ki o si fi idaru-dapọ̀ wọn bò ara, bi ẹnipe ẹ̀wu.