3 Nwọn si fi ọ̀rọ irira yi mi ka kiri; nwọn si mba mi ja li ainidi.
4 Nipo ifẹ mi nwọn nṣe ọta mi: ṣugbọn emi ngba adura.
5 Nwọn si fi ibi san ire fun mi, ati irira fun ifẹ mi.
6 Yan enia buburu tì i: jẹ ki Olufisùn ki o duro li ọwọ ọtún rẹ̀.
7 Nigbati a o ṣe idajọ rẹ̀, ki a da a lẹbi: ki adura rẹ̀ ki o di ẹ̀ṣẹ;
8 Ki ọjọ rẹ̀ ki o kuru; ki ẹlomiran ki o rọpo iṣẹ rẹ̀.
9 Ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alainibaba, ki aya rẹ̀ ki o di opó.