7 Nigbati a o ṣe idajọ rẹ̀, ki a da a lẹbi: ki adura rẹ̀ ki o di ẹ̀ṣẹ;
8 Ki ọjọ rẹ̀ ki o kuru; ki ẹlomiran ki o rọpo iṣẹ rẹ̀.
9 Ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alainibaba, ki aya rẹ̀ ki o di opó.
10 Jẹ ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o di alarinkiri, ti nṣagbe: ki nwọn ki o ma tọrọ onjẹ jina si ibi ahoro wọn.
11 Jẹ ki alọnilọwọ-gbà ki o mu ohun gbogbo ti o ni; ki alejo ki o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ.
12 Ki ẹnikẹni ki o má wà lati ṣãnu fun u: má si ṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o si lati ṣe oju rere fun awọn ọmọ rẹ̀ alainibaba.
13 Ki a ke ati ọmọ-de-ọmọ rẹ̀ kuro, ati ni iran ti mbọ̀ ki orukọ wọn ki o parẹ.