4 Fun ẹni-diduro-ṣinṣin ni imọlẹ mọ́ li òkunkun: olore-ọfẹ, o si kún fun ãnu, o si ṣe olododo.
5 Enia rere fi oju-rere hàn, a si wínni: imoye ni yio ma fi là ọ̀na iṣẹ rẹ̀.
6 Nitoriti a kì yio yi i nipò pada lailai: olododo yio wà ni iranti titi aiye.
7 Kì yio bẹ̀ru ihin buburu: aiya rẹ̀ ti mu ọ̀na kan, o gbẹkẹle Oluwa.
8 Aiya rẹ̀ ti mulẹ, kì yio bẹ̀ru, titi yio fi ri ifẹ rẹ̀ lori awọn ọta rẹ̀.
9 O ti fún ka, o ti fi fun awọn olupọnju; ododo rẹ̀ duro lailai; ọlá li a o fi gbé iwo rẹ̀ ga.
10 Awọn enia buburu yio ri i, inu wọn o si bajẹ; yio pa ehin rẹ̀ keke, yio si yọ́ danu: ifẹ awọn enia buburu yio ṣegbe.