1 INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa.
2 Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu.
3 Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan.
4 Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa.
5 Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi.
6 Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere.
7 Ki alafia ki o wà ninu odi rẹ, ati ire ninu ãfin rẹ.