1 AWỌN ti o gbẹkẹle Oluwa yio dabi òke Sioni, ti a kò le ṣi ni idi, bikoṣepe o duro lailai.
2 Bi òke nla ti yi Jerusalemu ka, bẹ̃li Oluwa yi awọn enia rẹ̀ ka lati isisiyi lọ ati titi lailai.
3 Nitori ti ọpá awọn enia buburu kì yio bà le ipin awọn olododo: ki awọn olododo ki o má ba fi ọwọ wọn le ẹ̀ṣẹ.
4 Oluwa ṣe rere fun awọn ẹni-rere, ati fun awọn ti aiya wọn duro ṣinṣin.
5 Bi o ṣe ti iru awọn ti nwọn yà si ipa ọ̀na wiwọ wọn: Oluwa yio jẹ ki wọn lọ pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn alafia yio wà lori Israeli.