3 Obinrin rẹ yio dabi àjara rere eleso pupọ li arin ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yio dabi igi olifi yi tabili rẹ ka.
4 Kiyesi i, pe bẹ̃li a o busi i fun ọkunrin na, ti o bẹ̀ru Oluwa.
5 Ki Oluwa ki o busi i fun ọ lati Sioni wá, ki iwọ ki o si ma ri ire Jerusalemu li ọjọ aiye rẹ gbogbo.
6 Bẹ̃ni ki iwọ ki o si ma ri ati ọmọ-de-ọmọ rẹ: ati alafia lara Israeli.