6 Bi emi kò ba ranti rẹ, jẹ ki ahọn mi ki o lẹ̀ mọ èrìgì mi; bi emi kò ba fi Jerusalemu ṣaju olori ayọ̀ mi gbogbo.
7 Oluwa, ranti ọjọ Jerusalemu lara awọn ọmọ Edomu, awọn ẹniti nwipe, Wó o palẹ, wó o palẹ, de ipilẹ rẹ̀!
8 Iwọ, ọmọbinrin Babeli, ẹniti a o parun; ibukún ni fun ẹniti o san a fun ọ bi iwọ ti hù si wa.
9 Ibukún li ẹniti o mu, ti o si fi ọmọ wẹwẹ rẹ ṣán okuta.