4 Gbogbo awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ kò ha ni ìmọ? awọn ẹniti njẹ enia mi bi ẹni jẹun, nwọn kò si kepè Oluwa.
5 Nibẹ ni ẹ̀ru bà wọn gidigidi: nitoriti Ọlọrun mbẹ ninu iran olododo.
6 Ẹnyin dojutì ìmọ awọn talaka, ṣugbọn Oluwa li àbo rẹ̀.
7 Tani yio fi igbala fun Israeli lati Sioni jade wá! nigbati Oluwa ba mu ikólọ awọn enia rẹ̀ pada bọ̀, Jakobu yio yọ̀, inu Israeli yio si dùn.