11 Yọ mi, ki o si gbà mi lọwọ awọn ọmọ àjeji, ẹnu ẹniti nsọ̀rọ asan, ati ọwọ ọtún wọn jẹ ọwọ ọtún eke:
12 Ki awọn ọmọkunrin wa, ki o dabi igi gbigbin ti o dagba ni igba-ewe wọn; ki awọn ọmọbinrin wa ki o le dabi ọwọ̀n igun-ile, ti a ṣe lọnà bi afarawe ãfin.
13 Ki aká wa ki o le kún, ki o ma funni li oniruru iṣura: ki awọn agutan wa ki o ma bi ẹgbẹgbẹrun ati ẹgbẹgbẹrun mẹwa ni igboro wa:
14 Ki awọn malu wa ki o le rẹrù; ki o má si ikọlù, tabi ikolọ jade: ki o má si aroye ni igboro wa.
15 Ibukún ni fun awọn enia, ti o mbẹ ni iru ìwa bẹ̃: nitõtọ, ibukún ni fun awọn enia na, ti ẹniti Ọlọrun Oluwa iṣe.