1 EMI o gbé ọ ga, Ọlọrun mi, ọba mi; emi o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ lai ati lailai.
2 Li ojojumọ li emi o ma fi ibukún fun ọ; emi o si ma yìn orukọ rẹ lai ati lailai.
3 Titobi li Oluwa, o si ni iyìn pupọ̀-pupọ̀; awamaridi si ni titobi rẹ̀.
4 Iran kan yio ma yìn iṣẹ rẹ de ekeji, yio si ma sọ̀rọ iṣẹ agbara rẹ.
5 Emi o sọ̀rọ iyìn ọla-nla rẹ ti o logo, ati ti iṣẹ iyanu rẹ.