17 Olododo li Oluwa li ọ̀na rẹ̀ gbogbo, ati alãnu ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo.
18 Oluwa wà leti ọdọ gbogbo awọn ti nkepè e, leti ọdọ gbogbo ẹniti nkepè e li otitọ.
19 Yio mu ifẹ awọn ti mbẹ̀ru rẹ̀ ṣẹ: yio gbọ́ igbe wọn pẹlu, yio si gbà wọn.
20 Oluwa da gbogbo awọn ti o fẹ ẹ si: ṣugbọn gbogbo enia buburu ni yio parun.
21 Ẹnu mi yio ma sọ̀rọ iyìn Oluwa: ki gbogbo enia ki o si ma fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́ lai ati lailai.