1 Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga.
2 Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀.
3 Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ.
4 Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun.
5 Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn.