1 ỌLỌRUN, pa mi mọ́: nitori iwọ ni mo gbẹkẹ mi le.
2 Ọkàn mi, iwọ ti wi fun Oluwa pe, Iwọ li Oluwa mi: emi kò ni ire kan lẹhin rẹ.
3 Si awọn enia mimọ́ ti o wà li aiye, ani si awọn ọlọla, lara ẹniti didùn inu mi gbogbo gbe wà.
4 Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi.
5 Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro.
6 Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere.