4 Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi.
5 Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro.
6 Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere.
7 Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru.
8 Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò.
9 Nitorina ni inu mi ṣe dùn, ti ogo mi si nyọ̀; ara mi pẹlu yio simi ni ireti.
10 Nitori iwọ kì yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bẹ̃ni iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ.