6 Ijadelọ rẹ̀ ni lati opin ọrun wá, ati ayika rẹ̀ si de ipinlẹ rẹ̀: kò si si ohun ti o fi ara pamọ́ kuro ninu õru rẹ̀.
7 Ofin Oluwa pé, o nyi ọkàn pada: ẹri Oluwa daniloju, o nsọ òpè di ọlọgbọ́n.
8 Ilana Oluwa tọ́, o nmu ọkàn yọ̀: aṣẹ Oluwa ni mimọ́, o nṣe imọlẹ oju.
9 Ẹ̀ru Oluwa mọ́, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn.
10 Nwọn jù wura daradara pupọ; nwọn si dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin.
11 Pẹlupẹlu nipa wọn li a ti ṣi iranṣẹ rẹ leti; ati ni pipamọ́ wọn ere pipọ̀ mbẹ.
12 Tali o le mọ̀ iṣina rẹ̀? wẹ̀ mi mọ́ kuro ninu iṣiṣe ìkọkọ mi.