1 ỌBA yio ma yọ̀ li agbara rẹ, Oluwa; ati ni igbala rẹ, yio ti yọ̀ pọ̀ to!
2 Iwọ ti fi ifẹ ọkàn rẹ̀ fun u, iwọ kò si dù u ni ibère ẹnu rẹ̀.
3 Nitori iwọ ti fi ibukún ore kò o li ọ̀na, iwọ fi ade kiki wura de e li ori.
4 O tọrọ ẹmi lọwọ rẹ, iwọ si fi fun u, ani ọjọ gigùn lai ati lailai.
5 Ogo rẹ̀ pọ̀ ni igbala rẹ: iyìn ati ọlánla ni iwọ fi si i lara.