7 Nitori ti ọba gbẹkẹle Oluwa, ati nipa ãnu Ọga-ogo kì yio ṣipò pada.
8 Ọwọ rẹ yio wá gbogbo awọn ọta rẹ ri: ọwọ ọtún rẹ ni yio wá awọn ti o korira rẹ ri.
9 Iwọ o ṣe wọn bi ileru onina ni igba ibinu rẹ: Oluwa yio gbé wọn mì ni ibinu rẹ̀, iná na yio si jó wọn pa.
10 Eso wọn ni iwọ o run kuro ni ilẹ, ati irú-ọmọ wọn kuro ninu awọn ọmọ enia.
11 Nitori ti nwọn nrò ibi si ọ: nwọn ngbìro ete ìwa-ibi, ti nwọn kì yio le ṣe.
12 Nitorina ni iwọ o ṣe mu wọn pẹhinda, nigbati iwọ ba fi ọfà rẹ kàn ọsán si oju wọn.
13 Ki iwọ ki ó ma leke, Oluwa, li agbara rẹ; bẹ̃li awa o ma kọrin, ti awa o si ma yìn agbara rẹ.