22 Emi o sọ̀rọ orukọ rẹ fun awọn arakunrin mi: li awujọ ijọ li emi o ma yìn ọ,
23 Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ẹ yìn i; gbogbo ẹnyin iru-ọmọ Jakobu, ẹ yìn i logo: ki ẹ si ma bẹ̀ru rẹ̀ gidigidi, gbogbo ẹnyin irú-ọmọ Israeli.
24 Nitoriti kò kẹgan, bẹ̃ni kò korira ipọnju awọn olupọnju; bẹ̃ni kò pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara rẹ̀; ṣugbọn nigbati o kigbe pè e, o gbọ́.
25 Nipa tirẹ ni iyìn mi yio wà ninu ajọ nla, emi o san ẹjẹ́ mi niwaju awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.
26 Awọn olupọnju yio jẹ, yio tẹ́ wọn lọrun: awọn ti nwá Oluwa yio yìn i: ọkàn nyin yio wà lailai:
27 Gbogbo opin aiye ni yio ranti, nwọn o si yipada si Oluwa: ati gbogbo ibatan orilẹ-ède ni yio wolẹ-sìn niwaju rẹ̀.
28 Nitori ijọba ni ti Oluwa; on si ni Bãlẹ ninu awọn orilẹ-ède.