1 OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini.
2 O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọ́rọ́.
3 O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀.
4 Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu.