2 Nitoriti o fi idi rẹ̀ sọlẹ lori okun, o si gbé e kalẹ lori awọn iṣan-omi.
3 Tani yio gùn ori oke Oluwa lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ́ rẹ̀?
4 Ẹniti o li ọwọ mimọ́, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti kò si bura ẹ̀tan.
5 On ni yio ri ibukún gbà lọwọ Oluwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun igbala rẹ̀.
6 Eyi ni iran awọn ti nṣe afẹri rẹ̀, ti nṣe afẹri rẹ, Ọlọrun Jakobu.
7 Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa.
8 Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara, Oluwa ti o lagbara li ogun.