1 EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi.
2 Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da.
3 Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho.
4 Kọrin si Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́, ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀.
5 Nitoripe, ni iṣẹju kan ni ibinu rẹ̀ ipẹ́, li ojurere rẹ̀ ni ìye gbe wà; bi ẹkun pẹ di alẹ kan, ṣugbọn ayọ̀ mbọ li owurọ.
6 Ati ninu alafia mi, emi ni, ipò mi kì yio pada lailai.
7 Oluwa, nipa oju-rere rẹ, iwọ ti mu òke mi duro ṣinṣin: nigbati iwọ pa oju rẹ mọ́, ẹnu yọ mi.