11 Emi di ẹni-ẹ̀gan lãrin awọn ọta mi gbogbo, pẹlupẹlu lãrin awọn aladugbo mi, mo si di ẹ̀ru fun awọn ojulumọ mi: awọn ti o ri mi lode nyẹra fun mi.
12 Emi ti di ẹni-igbagbe kuro ni ìye bi okú: emi dabi ohun-elo fifọ́.
13 Nitori ti emi ti ngbọ́ ẹ̀gan ọ̀pọ enia: ẹ̀ru wà niha gbogbo: nigbati nwọn ngbimọ pọ̀ si mi, nwọn gbiro ati gbà ẹmi mi kuro.
14 Ṣugbọn emi gbẹkẹle ọ, Oluwa: emi ni, Iwọ li Ọlọrun mi.
15 Igba mi mbẹ li ọwọ rẹ: gbà mi li ọwọ awọn ọta mi, ati li ọwọ awọn ti nṣe inunibini si mi,
16 Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara: gbà mi nitori ãnu rẹ.
17 Máṣe jẹ ki oju ki o tì mi, Oluwa; nitori ti emi nkepè ọ; enia buburu ni ki oju ki o tì, awọn ni ki a mu dakẹ ni isa-okú.