3 Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: nitorina nitori orukọ rẹ ma ṣe itọ́ mi, ki o si ma ṣe amọ̀na mi.
4 Yọ mi jade ninu àwọn ti nwọn nà silẹ fun mi ni ìkọkọ: nitori iwọ li ãbo mi.
5 Li ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le: iwọ li o ti rà mi pada, Oluwa Ọlọrun otitọ.
6 Emi ti korira awọn ẹniti nfiyesi eke asan: ṣugbọn emi gbẹkẹle Oluwa.
7 Emi o yọ̀, inu mi yio si dùn ninu ãnu rẹ: nitori ti iwọ ti rò ti iṣẹ́ mi; iwọ ti mọ̀ ọkàn mi ninu ipọnju;
8 Iwọ kò si sé mi mọ́ si ọwọ ọta nì: iwọ fi ẹsẹ mi tẹlẹ ni ibi àye nla.
9 Ṣãnu fun mi, Oluwa, nitori ti emi wà ninu iṣẹ́: oju mi fi ibinujẹ run, ọkàn mi ati inu mi.