1 IBUKÚN ni fun awọn ti a dari irekọja wọn jì, ti a bò ẹ̀ṣẹ wọn mọlẹ.
2 Ibukún ni fun ọkunrin na ẹniti Oluwa kò kà ẹ̀ṣẹ si lọrun, ati ninu ẹmi ẹniti ẹ̀tan kò si.
3 Nigbati mo dakẹ, egungun mi di gbigbo nitori igbe mi ni gbogbo ọjọ.
4 Nitori li ọsan ati li oru, ọwọ rẹ wuwo si mi lara: omi ara mi si dabi ọdá-ẹ̀run.
5 Emi jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ mi li emi kò si fi pamọ́. Emi wipe, emi o jẹwọ ìrekọja mi fun Oluwa: iwọ si dari ẹbi ẹ̀ṣẹ mi jì.
6 Nitori eyi li olukulùku ẹni ìwa-bi-ọlọrun yio ma gbadura si ọ ni igba ti a le ri ọ: nitõtọ ninu iṣan-omi nla, nwọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ̀.
7 Iwọ ni ibi ipamọ́ mi: iwọ o pa mi mọ́ kuro ninu iṣẹ́; iwọ o fi orin igbala yi mi ka kiri.